ISANLU ISIN

www.isanluisin.webs.com

ORIKI IDILE

ORIKI IMOORO (Presented by Joshua Dare Moriyonu)
Omo ori oloye, Omo Ayobi-ere
Ogbelenje Ori asa
Ologun gangan lori esin
Oropa tontibon, oretu tagbeltagbe
Oko borokinni san Anike, Oko winjobi
Opa baba mesin lese, oko Kapola
Sasa eniyan niferu lehin bee sinile
Taja teran nifeni loju eni
Tanifenilehin, bikosomo eni
Omo Aworinde, Omo Ajisola Ogun
Asorogun bi igi Obobo
Omo Onibedo, Oluju oja, abaja girimolode
Omo ogede gbepado sebi egungun
Patako efon kakaka nisaja lenu
Omo, Omo dunmoye, Omo Ajigbotifa
Omo
amowe be isin ape lomi be eja
Omo aleniloye, Omo ile maakun
Omo Oluju oja, omo mumu aro
Mumu aro ekan tobe, ekan esin kokan teniyan
Omo Amosi oku obo,
Omo akutan geri esin
Namu ebi meji loro,
Namu ibabimeji apakan mo
Omo Olomugo egba,
Omo ariyan wogun,
Obun emara, obun mara tan,
Kotun mon na Omo Olowo eyo
Amosi, Omo Oloja ti won ki mugba na
Jebete ni won
nfina tiwon
Kiki penkuku lodo oro
Omo Oba Akikanmekun lomugo
Omo Adifa gberu,
Omo eleja gbagba loro
Omo eleja akuugbe.

OKE-EPA, OKE-SANLU and ILE-OLOGBA (Submitted by Segun Ajide)Note: These 3 compounds have the same ORIKI mainly because they are families of the same mother.

Egba omo Lisabi Iyanyan afinran maje bi,

Mo sipe mo saaloo kihan mu ita yinmi ni ile asanlu

Igi pelebe ni han gbe lemi lowo ni ile baba wa.

Ofere owu ni han mu sa tokun oro nile Asanlu.

Iyanyan nimi afinran mo je bi awa lomo igi kan gogoro,

Omo igi kan gagara yoya dina lesa nile Asanlu ee

Jeki eru elesa lo ko ko jeki wo fa elesa naa tokoo bo;

Oyaju iyawo lole loo ko iyun wa igba yawo lole di igba ide odogba lan ja.

Omo okun lesa awon to yawo a maa kode,

Awon ti o yawo a maa ko awon baba ti yiyawo,

Tai yawo ni o koyun merindinlogun mo da somo lese moda somo lowo,

Mo niu yoku kanti omo keke ti kaa mi oko yin mi oko yin ran-an-mi,

Owo okuta ogbagi dun-un joko. Bo fun ni lowo a fun mi lomo.

Oun naa lo fun mi lomo agbe se ye.

 

 

Orin:

Ewee gboun oroo (2x) Ita nke yunmu yunmu,

ewee gboun oro, egbo abee gbo oo (2x)

Ha leko sebu oo egbo abe o gbo oo

Solo:- Ita o (All) Oro (2x)

Solo:- Asanlu Oro nbo ooo

All:- Oro Oro akee oro

Solo:- Ologba Oro nbo ooo

All:- Oro Oro akee oro

Solo:- Abi o somo oro ni le yi mo oo

All:- Odede lawa ao bi esu oooooo

Ita oooo, Oro oooooooooo......

 

IDI-OGUN, AIYETORO and ILE-LOKE

IDI-OGUN ati AIYETORO je OMO IYA KAN. ILE-LOKE je OMO BABA WON. The 3 compounds have the same ORIKI. (Submitted by Segun Ajide) 

Mojo suke, omo amowo oko lemi ale eyaka lafo,

Okanna keke, omo abiti owo, owo iya o too na, ti baba lo san pupo.

Elefun dere, arola siyan, ojo oo pa ewaa mi danu, o ba tete mewa ni ko mi

Omo anide ni gbongan mojo oya, oroso meji gba yigiyigi,

Omo osupaa na ja omo onigbaa aje.

Omo amelubo se ya na amu igba pete won owo eyo,

owo la mu molu eka gbin lafo,

owo wa wale. eka wa wu sesese.

Omo ise e se obinrin ako

Iya o je obirin okanna,

Obirin okanna to ba wi iya nje oun, ile loti gbe iya re wa;

Bonide kode lona kosin mi,

Kan osun mi lo tuu tuu,

Omo ogede ose gun lafo,

Omo asopa di win,

Mo satorin di monle lafo,

Atorin laa se loro ha

akii se egungun.

Omo elubo esi bakaje,

Tape nyo ape lenu,

Taja nkiri bale......etc

 

 

....Send your compounds oriki to isanlusin@gmail.com